Àwọn Ọba Keji 14:22-24 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Asaraya tún ìlú Elati kọ́, ó sì dá a pada fún Juda lẹ́yìn ikú baba rẹ̀.

23. Ní ọdún kẹẹdogun tí Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda ni Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli jọba ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkanlelogoji.

24. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA; ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.

Àwọn Ọba Keji 14