16. Ó kó gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì mú ẹ̀gún ọ̀gàn ati òṣùṣú, ó fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n.
17. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Penueli, ó wó ilé ìṣọ́ wọn, ó sì pa àwọn ọkunrin ìlú náà.
18. Lẹ́yìn náà, ó bi Seba ati Salimuna pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí ẹ pa ní Tabori wà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o ti rí gan-an ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn náà rí, gbogbo wọn dàbí ọmọ ọba.”
19. Ó dáhùn, ó ní, “Arakunrin mi ni wọ́n, ìyá kan náà ni ó bí wa. Bí OLUWA ti wà láàyè, bí ó bá jẹ́ pé ẹ dá wọn sí ni, ǹ bá dá ẹ̀yin náà sí.”
20. Ó bá pe Jeteri àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Dìde, kí o sì pa wọ́n,” ṣugbọn ọmọ náà kò fa idà rẹ̀ yọ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á, nítorí ọmọde ni.
21. Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn.