4. OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri,nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu,ilẹ̀ mì tìtì,omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́,ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀.
5. Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA,àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli.
6. Ní ìgbà ayé Ṣamgari, ọmọ Anati,ati nígbà ayé Jaeli, ọ̀wọ́ èrò kò rin ilẹ̀ yìí mọ́,àwọn arìnrìnàjò sì ń gba ọ̀nà kọ̀rọ̀.
7. Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá,gbogbo ìlú di àkọ̀tì,títí tí ìwọ Debora fi dìde,bí ìyá, ní Israẹli.