4. Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́ àwọn aláìní jẹ, tí ẹ múra láti pa àwọn talaka run lórí ilẹ̀ patapata.
5. Ẹ̀ ń sọ pé: “Nígbà wo ni ìsinmi oṣù titun yóo parí, kí á lè rí ààyè ta ọkà wa? Nígbà wo sì ni ọjọ́ ìsinmi yóo kọjá, kí á lè rí ààyè ta alikama, kí á lè gbówó lé ọjà wa, kí á sì lo òṣùnwọ̀n èké, láti rẹ́ àwọn oníbàárà wa jẹ;
6. kí á lè fi fadaka ra talaka, kí á lè ta aláìní, kí á sì fi owó rẹ̀ ra bàtà, kí á sì ta alikama tí kò dára?”
7. OLUWA ti fi ògo Jakọbu búra; ó ní, “Dájúdájú n kò ní gbàgbé ẹyọ kan ninu iṣẹ́ ọwọ́ yín.
8. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ilẹ̀ náà mì tìtì nítorí ọ̀rọ̀ yìí kí àwọn eniyan tí ń gbé orí rẹ̀ sì máa ṣọ̀fọ̀? Gbogbo rẹ̀ yóo ru sókè bí odò Naili, yóo máa lọ sókè sódò, yóo sì fà bí odò Naili ti Ijipti.
9. Ní ọjọ́ náà, n óo mú kí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́kanrí, ilẹ̀ yóo sì ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.
10. N óo yí àsè àjọ̀dún yín pada sí ọ̀fọ̀, n óo sọ orin yín di ẹkún; n óo sán aṣọ ìbànújẹ́ mọ́ gbogbo yín nídìí, n óo sì mú kí orí gbogbo yín pá; ẹ óo dàbí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo, ọjọ́ náà yóo korò ju ewúro lọ.”
11. OLUWA Ọlọrun ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo rán ìyàn sí ilẹ̀ náà; kì í ṣe ìyàn, oúnjẹ, tabi ti omi, ìran láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni kò ní sí.