Amosi 8:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA Ọlọrun, tún fi ìran mìíràn hàn mí. Lójú ìran, mo rí agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan.

2. OLUWA bèèrè pé, “Amosi, kí ni ò ń wò yìí?” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni.” OLUWA bá sọ pé: “Òpin ti dé sí Israẹli, àwọn eniyan mi, n kò sì ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.

3. Nígbà tó bá yá, orin inú tẹmpili yóo di ẹkún, òkú yóo sùn lọ kítikìti níbi gbogbo, a óo kó wọn dà síta ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

4. Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rẹ́ àwọn aláìní jẹ, tí ẹ múra láti pa àwọn talaka run lórí ilẹ̀ patapata.

5. Ẹ̀ ń sọ pé: “Nígbà wo ni ìsinmi oṣù titun yóo parí, kí á lè rí ààyè ta ọkà wa? Nígbà wo sì ni ọjọ́ ìsinmi yóo kọjá, kí á lè rí ààyè ta alikama, kí á lè gbówó lé ọjà wa, kí á sì lo òṣùnwọ̀n èké, láti rẹ́ àwọn oníbàárà wa jẹ;

6. kí á lè fi fadaka ra talaka, kí á lè ta aláìní, kí á sì fi owó rẹ̀ ra bàtà, kí á sì ta alikama tí kò dára?”

7. OLUWA ti fi ògo Jakọbu búra; ó ní, “Dájúdájú n kò ní gbàgbé ẹyọ kan ninu iṣẹ́ ọwọ́ yín.

8. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ilẹ̀ náà mì tìtì nítorí ọ̀rọ̀ yìí kí àwọn eniyan tí ń gbé orí rẹ̀ sì máa ṣọ̀fọ̀? Gbogbo rẹ̀ yóo ru sókè bí odò Naili, yóo máa lọ sókè sódò, yóo sì fà bí odò Naili ti Ijipti.

Amosi 8