Aisaya 8:8-12 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.”

9. Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ!A óo fọ yín túútúú.Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè.Ẹ di ara yín ní àmùrè;a óo fọ yín túútúú.Ẹ di ara yín ní àmùrè,a óo fọ yín túútúú.

10. Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo.Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán.Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa.

11. Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní,

12. “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù.

Aisaya 8