2. Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò.Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀.Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀,ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ.Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so,ṣugbọn èso kíkan ni ó so.
3. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda,mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi.
4. Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe?Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn,kí ló dé tí ó fi so èso kíkan?
5. Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín.N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká,iná yóo sì jó o.N óo wó odi tí mo mọ yí i ká,wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
6. N óo jẹ́ kí ó di igbó,ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́,wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́.Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀.N óo pàṣẹ fún òjòkí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́.
7. Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun,àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀.Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan;ó ń retí ìwà òdodo,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe.