19. Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín.
20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i.
21. Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.”
22. Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”
23. OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀.
24. Àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ fí ń ṣe iṣẹ́ lóko yóo máa jẹ oko tí a fi iyọ̀ sí; tí a ti gbọn ìdọ̀tí kúrò lára rẹ̀.
25. Omi yóo máa ṣàn jáde láti orí gbogbo òkè gíga ati gbogbo òkè ńlá, ní ọjọ́ tí ọpọlọpọ yóo kú, nígbà tí ilé ìṣọ́ bá wó lulẹ̀.
26. Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn.
27. Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè,ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú;ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè.Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu;ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run.
28. Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀tí ó lè mu eniyan dé ọrùn.Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè,yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu.
29. Ẹ óo kọ orin kan bí orin alẹ́ ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́,inú yín yóo sì dùn bíi ti ẹni tí ń jó ijó fèrè lọsórí òkè OLUWA, àpáta Israẹli.
30. OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo,yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńláati ninu iná ajónirun;pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín.
31. Ìbẹ̀rù-bojo yóo mú àwọn ará Asirianígbà tí wọ́n bá gbóhùn OLUWA,nígbà tí ó bá fi kùmọ̀ rẹ̀ lù wọ́n.