Aisaya 2:13-20 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni,tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani;

14. ati gbogbo àwọn òkè ńláńlá,ati gbogbo òkè gíga,

15. ati gbogbo ilé-ìṣọ́ gígaati gbogbo odi tí ó lágbára,

16. ati gbogbo ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Taṣiṣi,ati gbogbo ọkọ̀ tí ó dára.

17. Àwọn ọlọ́kàn gíga yóo di ẹni ilẹ̀,a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà,

18. àwọn oriṣa yóo sì pòórá patapata.

19. Àwọn eniyan yóo sá sinu ihò àpáta,wọn yóo sì wọ inú ihò ilẹ̀ lọ,nígbà tí wọ́n bá ń sá fún ibinu OLUWA,ati ògo ọlá ńlá rẹ̀nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

20. Ní ọjọ́ náà,àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù,ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ.Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán.

Aisaya 2