Róòmù 7:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá.

11. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí àyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin se ikú pa mi.

12. Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára.

13. Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.

14. Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

15. Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń se. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ se gan an n kò se é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kóríra ni mo ń se.

16. Ṣùgbọ́n bí mo bá se ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára.

17. Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ se rí yìí kì í se èmi ni ó se é bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.

18. Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ mi. Èmi fẹ́ se èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe.

19. Níorí ohun tí èmi se kì í se ohun rere tí èmi fẹ́ láti se; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, éyí nì ni èmi ń se.

Róòmù 7