6. Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.
7. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀.
8. Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, yálà ní kíkú tàbí ní yíyè, ti Olúwa ni àwá jẹ́.
9. Nítorí ìdí èyí náà ni Kírísítì fi kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààye.
10. Èése nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arakùnrin rẹ lẹ́jọ́? tàbì èése tí ìwọ sì ń fi ojú ẹ̀gàn wo arakùnrin rẹ? Nítorí olúkúlùkù wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.
11. A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:“ ‘Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,’ ni Olúwa wí‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”
12. Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.
13. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yé dá ara wa lẹ́jọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má se fi òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arakùnrin yín.