Oníwàásù 12:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Rántí rẹ̀—kí okùn fàdákà tó já,tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;kí ìṣa tó fọ́ níbi ìṣun,tàbí kí àyíká-kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

7. Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà rí,tí ẹ̀mí yóò sì padà ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

8. “Aṣán! Aṣán!” ni Oníwàásù wí.“Gbogbo rẹ̀ aṣán ni!”

9. Kì í ṣe wí pé Oníwàásù jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.

10. Oníwàásù wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.

11. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí èso tí a kàn pọ̀ dáradára tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni.

12. Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ-ọ̀n mi, gba ìmọ̀ràn.Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.

Oníwàásù 12