11. Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin láti Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Étamù, wọ́n sì sọ fún Sámúsónì pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Fílístínì ní ń ṣe alákóṣo lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?”Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.”
12. Wọ́n wí pé, “Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.”Sámúsónì wí pé, “Ẹ búra fún mi pé, ẹ̀yin kì yóò fúnra yín pa mí.”
13. “Àwá gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, awa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn túntún méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà.
14. Bí ó ti sún mọ́ Léhì, àwọn Fílístínì ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
15. Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túntún kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.
16. Sámúsónì sì wí pé,“Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kanMo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kanMo ti pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.”