Onídájọ́ 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè jéró Sámúsónì mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láàyè láti wọlé.

2. Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, “Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣebí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jù lọ? Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.”

3. Sámúsónì dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Fílístínì ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.”

4. Òun sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjìméjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀.

Onídájọ́ 15