Nọ́ḿbà 9:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkúùkù fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn ò ní í gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra.

23. Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.

Nọ́ḿbà 9