32. Élíásárì ọmọ Árónì àlùfáà ni alákóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Léfì. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.
33. Ti Mérárì ni ìran Málì àti Múṣì, àwọn ni ìran Mérárì.
34. Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).
35. Olórí àwọn ìdílé ìran Mérárì ni Súríélì ọmọ Ábíháílì, wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.
36. Àwọn ìran Mérárì ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn;
37. Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.