9. Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”
10. Nígbà náà ni ìbínú Bálákì sì dé sí Bálámù. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀ta mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.
11. Nísinsìnyìí kúrò lọ́dọ̀ mi kíákíá kí o sì máa relé! Mo sọ wí pé màá sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa kò jẹ́ kí o gba èrè yìí.”
12. Bálámù dá Bálákì lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé,
13. ‘Kó dà bí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’?