Nọ́ḿbà 10:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.

14. Àwọn ìpín ti ibùdó Júdà ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Náṣónì ọmọ Ámínádábù ni ọ̀gágun wọn.

15. Nẹ̀taníẹ́lì ọmọ Ṣúárì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Ísákárì;

16. Élíábù ọmọ Hélónì ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì.

17. Nígbà náà ni wọ́n sọ tabánákù kalẹ̀ àwọn ọmọ Gáṣónì àti Mérárì tó gbé àgọ́ sì gbéra.

18. Àwọn ìpín ti ibùdó ti Rúbẹ́nì ló gbéra tẹ̀le wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Élísúrì ọmọ Sédúrì ni ọ̀gágun wọn.

Nọ́ḿbà 10