1. Olúwa sọ fún Mósè pé:
2. Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o má a lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín.
3. Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé ṣíwájú rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
4. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náa ni àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì yóò péjọ ṣíwájú rẹ.
5. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà oòrùn ni yóò gbéra.
6. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra.
7. Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má se fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀.
8. “Àwọn Ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀.
9. Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀ta tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì ránti yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta yín.