Mátíù 13:51-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

51. Jésù bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.”

52. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí a ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.”

53. Lẹ́yìn ti Jésù ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò lọ.

54. Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Ṣínágọ́gù, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá?

55. Kì í há ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ há kọ́ ni à ń pè ní Màríà bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jémísì, Jósẹ́fù, Símonì àti Júdásì bí?

56. Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

57. Inú bí wọn sí i.Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, “Wòlíì a máa lọ́lá ní ibòmíràn, àfi ní ilé ara rẹ̀ àti ní ìlú ara rẹ̀ nìkan ni wòlíì kò ti lọ́lá.”

Mátíù 13