Máàkù 15:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Pílátù sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”Jésù sì dáhùn pé, “Ìwọ wí.”

3. Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án.

4. Pílátù sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”

5. Ṣùgbọ́n Jésù kò da lohùn síbẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pílátù.

Máàkù 15