35. Ó sì lọ ṣíwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá.
36. Ó sì wí pé, “Á bà Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kìí ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò se èyí tí ìwọ fẹ́.”
37. Nígbà tí ó sì páda dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Pétérù pé, “Símónì, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi sọ́nà fún wákàtí kan?
38. Ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”
39. Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.