Lúùkù 19:31-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”

32. Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.

33. Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”

34. Wọ́n sì wí pé, “Olúwa ń fẹ́ lò ó.”

35. Wọ́n sì fà á tọ Jésù wá: wọ́n sì tẹ́ ẹ wọ́n sì gbé Jésù kà á.

36. Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.

Lúùkù 19