Léfítíkù 13:44-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Alárùn ni ọkùnrin náà: kò sì mọ́, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́ torí egbò tí ó wà ní orí rẹ̀.

45. “Kí ẹni tí àrùn náà wà ní ara rẹ̀ wọ àkísà. Kí ó má ṣe gé irun rẹ̀, kí ó daṣọ bo ìṣàlẹ̀ ojú rẹ̀ kí ó sì máa ké wí pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’

46. Gbogbo ìgbà tí àrùn náà bá wà ní ara rẹ̀; aláìmọ́ ni: kí ó máa dá gbé. Kí ó máa gbé lẹ́yìn ibùdó.

47. “Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá ba aṣọ kan jẹ́ yálà aṣọ onírun àgùtàn tàbí aṣọ funfun.

48. Ìbáà ṣe títa tàbí híhun tí ó jẹ́ aṣọ funfun tàbí irun àgùtàn, bóyá àwọ̀ tàbí ohun tí a fi àwọ̀ ṣe.

Léfítíkù 13