Jóòbù 42:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nigbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n báa jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì sìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a: Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owo kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.

12. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ju ìsáá jú rẹ̀ lọ; ẹgbàá-méje àgùntàn, ẹgbàá-mẹ́ta ràkùnmí, àti ẹgbẹ̀rún àjàgà ọdá-màlúù, àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

13. Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta.

14. Ó sì sọ orúkọ àkọ̀bí ní Jẹ́mímà, àti orúkọ èkejì ni Késíà àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kérén-hápúkì.

15. Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jóòbù; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn ninú àwọn arákùnrin wọn.

16. Lẹ́yìn èyí Jóòbù wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin.

17. Bẹ́ẹ̀ ni Jóòbù kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀

Jóòbù 42