10. Olúwa sì yí ìgbèkùn Jóòbù padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bù sí ohun gbogbo ti Jóòbù ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí
11. Nigbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n báa jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì sìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a: Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owo kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.
12. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ju ìsáá jú rẹ̀ lọ; ẹgbàá-méje àgùntàn, ẹgbàá-mẹ́ta ràkùnmí, àti ẹgbẹ̀rún àjàgà ọdá-màlúù, àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
13. Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta.
14. Ó sì sọ orúkọ àkọ̀bí ní Jẹ́mímà, àti orúkọ èkejì ni Késíà àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kérén-hápúkì.
15. Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jóòbù; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn ninú àwọn arákùnrin wọn.
16. Lẹ́yìn èyí Jóòbù wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin.