14. Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀,a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;
15. Tí ó sì gbàgbé pé, ẹ̀sẹ̀ lè tẹ̀ wọ́nfọ́, tàbí pé ẹranko ìgbẹ́ lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
16. Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bíẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀, láì ní ìbẹ̀rù;
17. Nítorí pé Ọlọ́run kò fún-un ní ọgbọ́n,bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.
18. Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó ganẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.
19. “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí? tàbí ṣéÌwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?
20. Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá;
21. Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ síagbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
22. Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kòsì fòó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.