16. Ó ti fà oró pamọ́lẹ̀ múu; ahọ́ngúnte ní yóò pa á.
17. Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi,odò tí ń sàn fún oyin àti ti òrí àmọ́.
18. Ohun tí ó ṣíṣẹ́ fún ni yóò mú unpadà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì yọ̀ nínú rẹ̀.
19. Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni talákà lára,ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n;Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
20. “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínúara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkán rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.