1. Jósẹ́fù sì subú lé baba rẹ̀, ó sunkún, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu.
2. Nígbà náà ni Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Ísírẹ́lì baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀,
3. Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Éjíbítì sì sọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.
4. Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Jósẹ́fù wí fún àwọn ará ilé Fáráò pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bámi sọ fún Fáráò.
5. ‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú: sin mi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kénánì.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ”
6. Fáráò wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.”