Jẹ́nẹ́sísì 47:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Fáráò.

3. Fáráò béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kín ni iṣẹ́ yín?”Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran”

4. Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, “A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kénánì, àwọn ohun-ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ. Nítorí náà jọ̀wọ́ má sàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì.”

5. Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, “Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ tọ̀ ọ́ wá,

6. Ilẹ̀ Éjíbítì sì nìyí níwájú rẹ: Mú àwọn arákùnrin rẹ tẹ̀dó sí ibi tí ó dára jù nínú ilẹ̀ náà. Jẹ́ kí wọn máa gbé ní Gósénì. Bí o bá sì mọ ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó ní ẹ̀bùn-ìtọ́jú ẹran, fi wọ́n ṣe olùtọ́jú ẹran-ọ̀sìn mi.”

7. Nígbà náà ni Jósẹ́fù mú Jákọ́bù baba rẹ̀ wọlé wá sí iwájú Fáráò. Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù súre fún Fáráò tán.

8. Fáráò béèrè pé, “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?”

9. Jákọ́bù sì dá Fáráò lóhùn, “Ọdún ìrìn-àjò ayé mi jẹ́ àádóje (130), ọjọ́ mi kò pọ̀, ó sì kún fún wàhálà, ṣíbẹ̀ kò ì tí ì tó ti àwọn baba mi.”

10. Nígbà náà ni Jákọ́bù tún súre fún Fáráò, ó sì jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀.

11. Joṣẹ́fù sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Éjíbítì, ó sì fún wọn ní ohun-ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbégbé Ráméṣéṣì bí Fáráò ti pàṣẹ.

12. Jósẹ́fù sì pèṣè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn.

Jẹ́nẹ́sísì 47