15. Èyí sì ni a ó fi dán-an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Fáráò bá wà láàyè, ẹ kì yóò kùró níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá síbí.
16. Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú àtìmọ́lé, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Fáráò ti ń bẹ láàyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!”
17. Ó sì fi gbogbo wọn sínú àtìmọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta.
18. Ní ọjọ́ kẹ́ta, Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run:
19. Tí ó bá jẹ́ pé olótìítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọkan nínú yín dúró ni àtìmọ́lé ní ìhín, nígbà tí àwọn yókù u yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa.
20. Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má baà kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.
21. Wọ́n ń sọ ọ́ láàrin ara wọn wí pé, “Dájúdájú a ń jìyà nítorí ohun tí a ṣe sí Jósẹ́fù. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
22. Rúbẹ́nì fèsì pé, “Ǹjẹ́ ń ò wí fún yín pé kí ẹ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ọmọdé-kùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Nisinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.”
23. Wọn kò sì mọ̀ pé, Jósẹ́fù ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.
24. Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Símónì kúrò láàrin wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.