Jẹ́nẹ́sísì 36:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Àwọn ọmọ Rúélì:Náhátì, Ṣérà, Ṣámà àti Mísà. Àwọn ni ọmọ-ọmọ Báṣémátì aya Ísọ̀.

14. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Óhólíbámà ọmọbìnrin Ánà ọmọ-ọmọ Ṣíbéónì: tí ó bí fún Ísọ̀:Jéúsì, Jálámì àti Kórà.

15. Wọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Ísọ̀:Àwọn ọmọ Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀:Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Kénásíà,

16. Kórà, Gátamù àti Ámálékì. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Élífásì ní Édómù wá, wọ́n jẹ́ ọmọ-ọmọ Ádà.

Jẹ́nẹ́sísì 36