7. Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Bẹ́tẹ́lì (Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn-án nígbà tí ó ń sá lọ fún arákùnrin rẹ̀.
8. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Dèbórà, olùtọ́jú Rèbékà kú, a sì sin-ín sábẹ́ igi Óàkù ní ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bákútì (Óákù Ẹkún).
9. Lẹ́yìn tí Jákọ́bù padà dé láti Padani-Árámù, Ọlọ́run tún fara hàn-án, ó sì súre fún un.
10. Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jákọ́bù ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jákọ́bù (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.
11. Ọlọ́run sì wí fún-un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára; máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀.