Jẹ́nẹ́sísì 12:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì, ó sì pàgọ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀. Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀ oòrùn, Háì wà ní ìlà oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.

9. Nígbà náà ni Ábúrámù tẹ̀ṣíwájú sí ìhà gúsù ni Gúúsù.

10. Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi.

11. Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Éjíbítì, ó wí fún Ṣáráì, aya rẹ̀ pé, “Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ,

12. nígbà tí àwọn ara Éjíbítì bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí.

13. Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”

14. Nígbà tí Ábúrámù dé Éjíbítì, àwọn ará Éjíbítì ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi.

15. Nígbà tí àwọn ìjòyè Fáráò sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú u Fáráò, Wọ́n sì mú un lọ sí ààfin,

Jẹ́nẹ́sísì 12