16. “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀ èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, n ó jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’
17. “Nítorí náà, sọ pé: ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì padà.’
18. “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn ó sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà kúrò.
19. N ó fún wọn ní ọ̀kan kan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; N ó mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, n ó sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran.
20. Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
21. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sórí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”
22. Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lókè orí wọn.