10. èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ orí kan àní Kírísítì.
11. Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́hìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀,
12. kí àwa tí ó jẹ́ àkóso ìrètí nínú Kírísítì lè jásí ìyìn ògo rẹ̀.
13. Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kírísítì nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Lẹ́yìn tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a lù yín ní òǹtẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀,
14. èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àsansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ìní Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.
15. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúro ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàárin yín nínú Jésù Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.