1 Ọba 11:25-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Résónì sì jẹ́ ọ̀ta Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì, ó ń pa kún ibi ti Hádádì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Résónì jọba ní Síríà, ó sì sòdì sí Ísírẹ́lì.

26. Bákan náà Jéróbóámù ọmọ Nébátì sì sọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì, ará Éfúrátì ti Sérédà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Sérúà.

27. Èyí sì ni ìdí tí ó fi sọ̀tẹ̀ sí ọba: Sólómónì kọ́ Mílò, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dáfídì baba rẹ̀.

28. Jéróbóámù jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Sólómónì sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Jóṣẹ́fù.

29. Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jéróbóámù ń jáde kúrò ní Jérúsálẹ́mù. Wòlíì Áhíjà ti Ṣílò sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá túntún. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko,

30. Áhíjà sì gbá agbádá túntún tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá

31. Nígbà náà ni ó sọ fún Jéróbóámù pé, “Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómónì, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.

1 Ọba 11