1 Ọba 11:23-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ọlọ́run sì gbé ọ̀ta mìíràn dìde sí Sólómónì, Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hádádésérì olúwa rẹ̀, ọba Sóbà.

24. Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dáfídì fi pa ogun Sóbà run; wọ́n sì lọ sí Dámásíkù, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jọba ní Dámásíkù.

25. Résónì sì jẹ́ ọ̀ta Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì, ó ń pa kún ibi ti Hádádì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Résónì jọba ní Síríà, ó sì sòdì sí Ísírẹ́lì.

26. Bákan náà Jéróbóámù ọmọ Nébátì sì sọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì, ará Éfúrátì ti Sérédà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Sérúà.

27. Èyí sì ni ìdí tí ó fi sọ̀tẹ̀ sí ọba: Sólómónì kọ́ Mílò, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dáfídì baba rẹ̀.

28. Jéróbóámù jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Sólómónì sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Jóṣẹ́fù.

29. Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jéróbóámù ń jáde kúrò ní Jérúsálẹ́mù. Wòlíì Áhíjà ti Ṣílò sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá túntún. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko,

30. Áhíjà sì gbá agbádá túntún tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá

31. Nígbà náà ni ó sọ fún Jéróbóámù pé, “Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómónì, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.

32. Ṣùgbọ́n nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, òun yóò ní ẹ̀yà kan.

33. Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì, Kémósì òrìṣà àwọn ará Móábù, àti Mííkámù òrìṣà àwọn ọmọ Ámónì, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómónì ti ṣe.

34. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Sólómónì; èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́.

1 Ọba 11