22. Fáráò sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?”Hádádì sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!”
23. Ọlọ́run sì gbé ọ̀ta mìíràn dìde sí Sólómónì, Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hádádésérì olúwa rẹ̀, ọba Sóbà.
24. Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dáfídì fi pa ogun Sóbà run; wọ́n sì lọ sí Dámásíkù, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jọba ní Dámásíkù.
25. Résónì sì jẹ́ ọ̀ta Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì, ó ń pa kún ibi ti Hádádì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Résónì jọba ní Síríà, ó sì sòdì sí Ísírẹ́lì.
26. Bákan náà Jéróbóámù ọmọ Nébátì sì sọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì, ará Éfúrátì ti Sérédà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Sérúà.
27. Èyí sì ni ìdí tí ó fi sọ̀tẹ̀ sí ọba: Sólómónì kọ́ Mílò, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dáfídì baba rẹ̀.