1 Kọ́ríńtì 13:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ìfẹ́ kì í huwa àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú.

6. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìsòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo sí òtítọ́.

7. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbógbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

8. Ìfẹ̀ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bún ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

9. Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọ tẹ̀lẹ́ ní apá kan.

10. Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apákan yóò dópin.

11. Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, emí a máa gbèrò bí èwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀.

12. Nítorí pé nísinsìnyìí àwa ń ríran bàìbàì nínú àwòjìjì; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsinyìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mímọ̀ pẹ̀lú.

13. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.

1 Kọ́ríńtì 13