12. Ẹ pada si odi agbara, ẹnyin onde ireti: ani loni yi emi sọ pe, emi o san a fun ọ ni igbàmejì.
13. Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara.
14. Oluwa yio si fi ara rẹ̀ hàn lori wọn, ọfà rẹ̀ yio si jade lọ bi mànamána: Oluwa Ọlọrun yio si fun ipè, yio si lọ ti on ti ãjà gusù.
15. Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dãbo bò wọn; nwọn o si jẹ ni run, nwọn o si tẹ̀ okuta kànna-kànna mọlẹ; nwọn o si mu, nwọn o si pariwo bi nipa ọti-waini; nwọn o si kún bi ọpọ́n, ati bi awọn igun pẹpẹ.
16. Oluwa Ọlọrun wọn yio si gbà wọn là li ọjọ na bi agbo enia rẹ̀: nitori nwọn o dabi awọn okuta ade, ti a gbe soke bi àmi lori ilẹ rẹ̀.