Sek 3:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O sì fi Joṣua olori alufa hàn mi, o duro niwaju angeli Oluwa, Satani si duro lọwọ ọtun rẹ̀ lati kọju ijà si i.

2. Oluwa si wi fun Satani pe, Oluwa ba ọ wi, iwọ Satani; ani Oluwa ti o ti yàn Jerusalemu, o ba ọ wi: igi iná kọ eyi ti a mu kuro ninu iná?

3. A si wọ̀ Joṣua li aṣọ ẽri, o si duro niwaju angeli na.

4. O si dahùn o wi fun awọn ti o duro niwaju rẹ̀ pe, Bọ aṣọ ẽri nì kuro li ara rẹ̀. O si wi fun u pe, Wò o, mo mu ki aiṣedẽde rẹ kuro lọdọ rẹ, emi o si wọ̀ ọ li aṣọ ẹyẹ.

5. Mo si wipe, Jẹ ki wọn fi lawàni mimọ́ wé e li ori. Nwọn si fi lawàni mimọ́ wé e lori, nwọn si fi aṣọ wọ̀ ọ. Angeli Oluwa si duro tì i.

6. Angeli Oluwa si tẹnu mọ fun Joṣua pe,

7. Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, bi iwọ o ba si pa aṣẹ mi mọ, iwọ o si ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa ãfin mi mọ pẹlu, emi o si fun ọ li àye ati rìn lãrin awọn ti o duro yi.

Sek 3