8. Nitorina ẹ duro dè mi, ni Oluwa wi, titi di ọjọ na ti emi o dide si ohun-ọdẹ: nitori ipinnu mi ni lati kó awọn orilẹ-ède jọ, ki emi ki o le kó awọn ilẹ ọba jọ, lati dà irúnu mi si ori wọn, ani gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a o fi iná owu mi jẹ gbogbo aiye run.
9. Nitori nigbana li emi o yi ède mimọ́ si awọn enia, ki gbogbo wọn ki o le ma pè orukọ Oluwa, lati fi ọkàn kan sìn i.
10. Lati oke odò Etiopia awọn ẹlẹbẹ̀ mi, ani ọmọbinrin afunká mi, yio mu ọrẹ mi wá.
11. Li ọjọ na ni iwọ kì yio tijú, nitori gbogbo iṣe rẹ, ninu eyiti iwọ ti dẹṣẹ si mi: nitori nigbana li emi o mu awọn ti nyọ̀ ninu igberaga rẹ kuro lãrin rẹ, iwọ kì yio si gberaga mọ li oke mimọ́ mi.