11. Li ọjọ na ni iwọ kì yio tijú, nitori gbogbo iṣe rẹ, ninu eyiti iwọ ti dẹṣẹ si mi: nitori nigbana li emi o mu awọn ti nyọ̀ ninu igberaga rẹ kuro lãrin rẹ, iwọ kì yio si gberaga mọ li oke mimọ́ mi.
12. Emi o fi awọn otòṣi ati talakà enia silẹ pẹlu lãrin rẹ, nwọn o si gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa.
13. Awọn iyokù Israeli kì yio hùwa ibi, bẹ̃ni nwọn kì yio sọ̀rọ eke, bẹ̃ni a kì yio ri ahọn arekerekè li ẹnu wọn: ṣugbọn nwọn o jẹun nwọn o si dubulẹ, ẹnikan kì yio si dẹ̀ruba wọn.
14. Kọrin, iwọ ọmọbinrin Sioni; kigbe, iwọ Israeli; fi gbogbo ọkàn yọ̀, ki inu rẹ ki o si dùn, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu.
15. Oluwa ti mu idajọ rẹ wọnni kuro, o ti tì ọta rẹ jade: ọba Israeli, ani Oluwa, mbẹ lãrin rẹ: iwọ kì yio si ri ibi mọ.
16. Li ọjọ na a o wi fun Jerusalemu pe, Iwọ má bẹ̀ru: ati fun Sioni pe, Má jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o dẹ̀.
17. Oluwa Ọlọrun rẹ li agbara li ãrin rẹ; yio gbà ni là, yio yọ̀ li ori rẹ fun ayọ̀; yio simi ninu ifẹ rẹ̀, yio fi orin yọ̀ li ori rẹ.
18. Emi o kó awọn ti o banujẹ fun ajọ mimọ́ jọ awọn ti o jẹ tirẹ, fun awọn ti ẹgàn rẹ̀ jasi ẹrù.