6. Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli:
7. Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, Ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ.
8. Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ.
9. Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin.
10. Kì si iṣe kìki eyi; ṣugbọn nigbati Rebekka pẹlu lóyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa;
11. Nitori nigbati a kò ti ibí awọn ọmọ na, bẹ̃ni nwọn kò ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti iyanfẹ ki o le duro, kì iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npè ni;)
12. A ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio ma sìn aburo,
13. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakọbu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira.
14. Njẹ awa o ha ti wi? Aiṣododo ha wà lọdọ Ọlọrun bi? Ki a má ri.
15. Nitori o wi fun Mose pe, Emi ó ṣãnu fun ẹniti emi ó ṣãnu fun, emi o si ṣe iyọ́nu fun ẹniti emi o ṣe iyọ́nu fun.
16. Njẹ bẹ̃ni kì iṣe ti ẹniti o fẹ, kì si iṣe ti ẹniti nsáre, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣãnu.
17. Nitori iwe-mimọ́ wi fun Farao pe, Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mã ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye.
18. Nitorina li o ṣe nṣãnu fun ẹniti o wù u, ẹniti o wù u a si mu u li ọkàn le.
19. Iwọ o si wi fun mi pe, Kili ó ha tun ba ni wi si? Nitori tali o ndè ifẹ rẹ̀ lọ̀na?
20. Bẹ̃kọ, iwọ enia, tani iwọ ti nda Ọlọrun lohùn? Ohun ti a mọ a ha mã wi fun ẹniti ti o mọ ọ pé, Ẽṣe ti iwọ fi mọ mi bayi?