Rom 9:2-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Pe mo ni ibinujẹ pupọ, ati ikãnu igbagbogbo li ọkàn mi.

3. Nitori mo fẹrẹ le gbadura pe ki a ké emi tikarami kuro lọdọ Kristi, nitori awọn ará mi, awọn ibatan mi nipa ti ara:

4. Awọn ẹniti iṣe Israeli; ti awọn ẹniti isọdọmọ iṣe, ati ogo, ati majẹmu, ati ifunnilofin, ati ìsin Ọlọrun, ati awọn ileri;

5. Ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo, Ọlọrun olubukún lailai. Amin.

6. Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli:

7. Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, Ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ.

8. Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ.

9. Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin.

10. Kì si iṣe kìki eyi; ṣugbọn nigbati Rebekka pẹlu lóyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa;

11. Nitori nigbati a kò ti ibí awọn ọmọ na, bẹ̃ni nwọn kò ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti iyanfẹ ki o le duro, kì iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npè ni;)

12. A ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio ma sìn aburo,

13. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakọbu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira.

14. Njẹ awa o ha ti wi? Aiṣododo ha wà lọdọ Ọlọrun bi? Ki a má ri.

15. Nitori o wi fun Mose pe, Emi ó ṣãnu fun ẹniti emi ó ṣãnu fun, emi o si ṣe iyọ́nu fun ẹniti emi o ṣe iyọ́nu fun.

16. Njẹ bẹ̃ni kì iṣe ti ẹniti o fẹ, kì si iṣe ti ẹniti nsáre, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣãnu.

17. Nitori iwe-mimọ́ wi fun Farao pe, Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mã ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye.

Rom 9