9. Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́ fun Abrahamu si ododo.
10. Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni.
11. O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu:
12. Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla.
13. Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ̀ pe, on ó ṣe arole aiye, kì iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ́.
14. Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ́ di asan, ileri si di alailagbara:
15. Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀.
16. Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ́, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; kì iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awọn ti inu igbagbọ́ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa,