15. Awọn ti nyọ̀, ẹ mã ba wọn yọ̀, awọn ti nsọkun, ẹ mã ba wọn sọkun.
16. Ẹ mã wà ni inu kanna si ara nyin. Ẹ máṣe tọju ohun gíga, ṣugbọn ẹ mã tẹle awọn onirẹlẹ. Ẹ máṣe jẹ ọlọ́gbọn li oju ara nyin.
17. Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. Ẹ mã pèse ohun ti o tọ́ niwaju gbogbo enia.
18. Bi o le ṣe, bi o ti wà ni ipa ti nyin, ẹ mã wà li alafia pẹlu gbogbo enia.
19. Olufẹ, ẹ máṣe gbẹsan ara nyin, ṣugbọn ẹ fi àye silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi ó gbẹsan.
20. Ṣugbọn bi ebi ba npa ọtá rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba ngbẹ ẹ, fun u li omi mu: ni ṣiṣe bẹ̃ iwọ ó kó ẹyín ina le e li ori.
21. Maṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi rere ṣẹgun buburu.