4. Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́.
5. Mose sá kọ̀we rẹ̀ pe, ẹniti o ba ṣe ododo ti iṣe ti ofin, yio yè nipa rẹ̀.
6. Ṣugbọn ododo ti iṣe ti igbagbọ́ sọ bayi pe, Máṣe wi li ọkàn rẹ pe, tani yio goke lọ si ọrun? (eyini ni, lati mu Kristi sọkalẹ:)
7. Tabi, tani yio sọkalẹ lọ si ọgbun? (eyini ni, lati mu Kristi goke ti inu okú wá).
8. Ṣugbọn kili o wi? Ọ̀rọ na wà leti ọdọ rẹ, li ẹnu rẹ, ati li ọkan rẹ: eyini ni, ọ̀rọ igbagbọ́, ti awa nwasu;