2. Nitori mo gbà ẹri wọn jẹ pe, nwọn ni itara fun Ọlọrun, ṣugbọn kì iṣe gẹgẹ bi ìmọ.
3. Nitori bi nwọn kò ti mọ ododo Ọlọrun, ti nwọn si nwá ọna lati gbé ododo ara wọn kalẹ, nwọn kò tẹriba fun ododo Ọlọrun.
4. Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́.
5. Mose sá kọ̀we rẹ̀ pe, ẹniti o ba ṣe ododo ti iṣe ti ofin, yio yè nipa rẹ̀.
6. Ṣugbọn ododo ti iṣe ti igbagbọ́ sọ bayi pe, Máṣe wi li ọkàn rẹ pe, tani yio goke lọ si ọrun? (eyini ni, lati mu Kristi sọkalẹ:)
7. Tabi, tani yio sọkalẹ lọ si ọgbun? (eyini ni, lati mu Kristi goke ti inu okú wá).
8. Ṣugbọn kili o wi? Ọ̀rọ na wà leti ọdọ rẹ, li ẹnu rẹ, ati li ọkan rẹ: eyini ni, ọ̀rọ igbagbọ́, ti awa nwasu;
9. Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là.
10. Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala.